Jump to content

Kollington Ayinla

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Kọ́láwọlé "Kollington" Ayinla (tí a bí ní ọdún 1953) jẹ́ òlòrín fújì ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó wá láti ilọta, èyí tí í ṣe abúlé kan tí ó wà ní gbangba ìlú ÌlọrinÌpínlẹ̀ Kwara, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn ènìyàn tún ma ń pe Kollington Ayinla ní Bàbá Alátíká, Kèbè-n-Kwara, àti Bàbá Alágbàdo.[1]

Ayinla ati olùbádíje ọ̀rẹ́ rẹ, Ayinde Barrister ni wọ́n fi sí ipò kanná àn gẹ́gẹ́ bí i àwọn òṣèré olórin méjì tí ó gbajúmọ̀ jùlọ tí wọ́n sì tún jẹ́ àwọn tí ó jẹ gàba lórí orin fújì láti ìgbàtí orin fújì ti bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ọdún 1970 sí àwọn ọdún 1990 ní àkókò tí orin fújì ti di ijó tí ó gbajúmọ̀ tí àwọn ènìyàn ń jó ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Laarin àwọn ọdún 1970 sí àwọn ọdún 1980, Kollington wà ní ipò kanna pẹ̀lú Barrister gẹgẹ bí i aṣíwájú àti gbajúmọ̀ fún àwọn orin fújì bí i àpàlà àti wákà ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Àwọn ẹlẹ́sìn mùsùlùmí ni wọ́n pọ̀jù nínú àwọn tí ń kọ àwọn orin fújì yí tí wọ́n sì ń ṣe àmúlò ohùn wọn láti kọ wọ́n ṣùgbọ́n tí wọn kò ṣe àmúlò gìtá láti le ṣe àfihàn ìjìnlẹ̀ ohùn orin ìbílẹ̀. Kollington bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gbígba orin sílẹ̀ fún EMI ti ilẹ̀ Nàìjíríà ní ọdún 1974, àti wípé ní ọdún 1978, iṣẹ́ orin kíkọ rẹ yọrí sókè fún ìgbà díẹ̀ ju ti barrister lọ ní àkókò tí ó mú Ìlu-Bàtá wọ inú orin fújì ( títí di àkókò yẹn, ìlù aláfisọ̀rọ̀ tàbí aláfùnpọ̀ ni wọ́n má ń lò fún orin fújì) èyí tí ó mú ìwúrí bá àwọn tí ó ń ra àwo orin fújì. Ní ọdún 1982, nígbàtí orin fújì bẹ̀rẹ̀ sí ní fi igbagágba pẹ̀lú orin jùjú gẹ́gẹ́ bí i orin ìbílẹ̀ tí ó gbajúmọ̀ jùlọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Kọllington ṣe ìdásílẹ̀ àmì ìdánimọ̀ orí àwo-orin tirẹ̀ tí ó pè ní kollington Records nípasẹ̀ èyí tí ó fi gbé àwo-orin ọgbọ̀n, ó kéré jù, jáde laarin ọdún márùn ún. Bí orin fújì ṣe ń gbajúmọ̀ si tí ̀atìlẹyìn àwọn olólùfẹ́ orin àwọn òṣèré méjèèjì yí si ń pọ̀ si nípasẹ̀ ríra àwo-orin wọn, bẹ́ ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìṣọ̀tá tí ó wà laarin Kollington àti Barrister n dinku.[2] Ní ọdún 1983, Kọllington àti Barrister ní ànfààní làti dúró ní ẹ̀gbẹ́ ara wọn nígbà tí wọ́n lọ bá wọn ṣọ̀fọ̀ níbi ìsìnkú Haruna Iṣọla tí í ṣe gbajúmọ̀ olórin àpàlà. Ní́ àárín àwọn ọdún 1980s ní ifagagbága tuntun òmíràn tún jẹyọ pẹ̀lú Salawa Abẹni, ọba wákà, ẹni tí ó ń sòkò ọ̀rọ̀ èébú sí kọllington Ayinla lórí oríṣiríṣi àwọn àwo-orin tí wọ́n gbé jáde àti èyí tí ó tako àwọn àwo-orin tí ó jáde. Ó jẹ́ ǹ kan ìbànújẹ́ pé àwọn tí kì i sọ èdè yòrùbá rí àwọn ọ̀rọ̀ àlùfànṣá yi gẹ́gẹ́ bí i àwọn ọ̀rọ̀ tí kò mú òye dání, bíòtilẹ̀jẹ́ wípé àfilọ̀ ẹ̀rú-ìlù àti orin afúnra yi kárí gbogbo àgbáyé.[3]

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1980s, Ayinla bẹ̀rẹ̀ ilé-iṣẹ́ àwo-orin tirẹ̀, èyí tí ó sọ ní Kollington Records láti má a ṣe àgbéjáde àwọn orin rẹ̀. Títí di òní yi, Kollington wà gẹ́gẹ́ bí i olórin aláìlẹ́gbẹ́, lẹ́yìn tí ó ti ṣe àkọsílẹ̀ àwo-orin àádọ́ta èyí tí ó jẹ́ wípé púpọ̀ nínú wọn ni wọ́n gbé jáde ní ilẹ̀ Nàìjíríà.[4]

Ní ọdún 2019, Ayinla sọ wípé níṣe ni ò un fi iṣẹ́ ológun sílẹ̀ fún iṣẹ́ orin.[5]

  1. Okanlawon, Taiwo (2020-08-18). "Saheed Osupa, Pasuma celebrate Fuji legend, Kollington Ayinla on birthday". P.M. News. Retrieved 2021-02-19. 
  2. "Alhaji Chief Kollington Ayinla & His Fuji". Sounds of the Universe. Retrieved 2021-02-24. 
  3. "African Music Encyclopedia: Ayinla Kollington". African Music Encyclopedia. Retrieved 2021-02-24. 
  4. "At 62, Kollington still hot in bed, says young wife". Vanguard News. 2015-08-15. Retrieved 2021-02-24. 
  5. "Why I dumped military for music–Kollington Ayinla". The Sun Nigeria. 2019-03-30. Retrieved 2021-02-24. 
pFad - Phonifier reborn

Pfad - The Proxy pFad of © 2024 Garber Painting. All rights reserved.

Note: This service is not intended for secure transactions such as banking, social media, email, or purchasing. Use at your own risk. We assume no liability whatsoever for broken pages.


Alternative Proxies:

Alternative Proxy

pFad Proxy

pFad v3 Proxy

pFad v4 Proxy